translation
dict
{ "en": "It is up to each believer . . .", "yo": "Ẹnì kọ̀ọ̀kan ló máa pinnu ìyẹn . . ." }
{ "en": "By refusing a blood transfusion they are not choosing to die, instead, they want quality treatment and first-rate medical assistance.", "yo": "Kì í ṣe pé wọ́n fẹ́ kú ni wọ́n ṣe ń sọ pé àwọn ò gbẹ̀jẹ̀, ṣe ni wọ́n fẹ́ ìtọ́jú tó péye àti àbójútó ìṣègùn tó dáa." }
{ "en": "Blood transfusions, in their view and from various medical standpoints, come with a risk because a person can contract AIDS or something else.", "yo": "Wọ́n mọ̀, àwọn oníṣègùn náà sì gbà pé ìgbẹ̀jẹ̀sára léwu torí pé ẹni tó gbẹ̀jẹ̀ sára lè kó àrùn Éèdì tàbí irú àrùn míì." }
{ "en": "Bloodless surgeries provide a higher guarantee, and I see from examining the statistics that wealthy people often prefer to forgo blood transfusions because this guarantees better protection from infections and complications.”", "yo": "Iṣẹ́ abẹ láìlo ẹ̀jẹ̀ ló fọkàn ẹni balẹ̀ jù, mo sì ti rí i nígbà tí mo ṣàyẹ̀wò àkọsílẹ̀ ìṣirò pé àwọn ọlọ́rọ̀ kì í sábà fẹ́ láti gbẹ̀jẹ̀ torí pé ìyẹn ni ò ní jẹ́ kí wọ́n kó àrùn tàbí kí wọ́n ní ìṣòro.”" }
{ "en": "Jehovah’s Witnesses and donations.", "yo": "Ojú tí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà fi ń wo ọrẹ." }
{ "en": "“A person can choose not to make any donations.", "yo": "“Ẹnì kan lè pinnu pé òun ò ní fi owó ṣètọrẹ." }
{ "en": "Theoretically speaking, one can actually attend meetings of Jehovah’s Witnesses his whole life and never contribute a single ruble or dollar.", "yo": "Ó ṣeé ṣe kí ẹnì kan fi gbogbo ọjọ́ ayé rẹ̀ lọ sí ìpàdé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kó má sì dá kọ́bọ̀." }
{ "en": "It is up to each individual whether to contribute or not.”", "yo": "Ọwọ́ ẹnì kọ̀ọ̀kan ló kù sí láti pinnu bóyá òun á fi owó ṣètọrẹ tàbí òun ò ní ṣe bẹ́ẹ̀.”" }
{ "en": "Although Dr. Ivanenko authoritatively testified that Jehovah’s Witnesses are conscientious, law-abiding Christians, the court ignored his arguments and sentenced all six brothers to various terms of imprisonment.", "yo": "Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọ̀mọ̀wé Ivanenko fi ìdánilójú jẹ́rìí sí i pé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kì í ṣe arúfin, wọ́n sì máa ń pa òfin mọ́, ilé ẹjọ́ kó àlàyé rẹ dà nù wọ́n sì ní kí àwọn arákùnrin mẹ́fẹ̀ẹ̀fà lọ lògbà tó yàtọ̀ síra lẹ́wọ̀n." }
{ "en": "As Russia continues to accuse our brothers falsely and imprison them unjustly, it remains our prayer that Jehovah bless our courageous and faithful fellow worshippers with the joy of his approval.—Psalm 109:2-4, 28.\"", "yo": "Bí orílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà ṣe ń bá a nìṣo láti máa fi ẹ̀sùn èké kan àwọn ará wa tí wọ́n sì ń fi wọ́n sẹ́wọ̀n láìtọ́, a ò ní yé gbàdúrà pé kí Jèhófà máa rọ̀jò ibùkún rẹ̀ sórí àwọn ará wa tí wọ́n jẹ́ onígboyà àti olóòótọ́ kí inú wọn lè máa dùn pé àwọn ní ìtẹ́wọ́gbà rẹ̀.—Sáàmù 109:2-4, 28.\"" }
{ "en": "\"On February 14, 2020, the Vilyuchinsk City Court convicted Brother Mikhail Popov and his wife, Sister Yelena Popova.", "yo": "\"Ní February 14, 2020, Ilé-Ẹjọ́ ìlú ńlá Vilyuchinsk dá Arákùnrin Mikhail Popov àti ìyàwó rẹ̀ Arábìnrin Yelena Popov lẹ́bi." }
{ "en": "The court fined them 350,000 rubles ($5,508 U.S.) and 300,000 rubles ($4,722 U.S.), respectively, but did not sentence them to any prison time.", "yo": "Ilé-Ẹjọ́ ní kí Arákùnrin Mikhail Popov san 350,000 rubles ($5,508 U.S.) owó ìtanràn, wọ́n sì ní kí ìyàwó rẹ̀ Arábìnrin Yelena Popov san 300,000 rubles ($4,722 U.S.), àmọ́ wọn ò fi wọ́n sẹ́wọ̀n rárá." }
{ "en": "They will both appeal their convictions.", "yo": "Àwọn méjèèjì máa pe ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn lórí ìdájọ́ yìí." }
{ "en": "Mikhail and Yelena were arrested in July 2018.", "yo": "Ìjọba mú Mikhail àti Yelena ní July 2018." }
{ "en": "Shortly afterward, they were released to await trial.", "yo": "Kò sì pẹ́ tí wọ́n fi wọ́n sílẹ̀, wọ́n sì ní kí wọ́n máa dúró de ìdájọ́ wọn." }
{ "en": "Since 2019, Russian courts have convicted 28 Jehovah’s Witnesses for their faith.", "yo": "Láti ọdún 2019, ilé-ẹjọ́ orílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà ti dá àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà méjìdínlọ́gbọ̀n (28) lẹ́bi nítorí ìgbàgbọ́ wọn." }
{ "en": "Ten of these brothers and sisters were convicted in just the last two months. However, these ten are not currently imprisoned.\"", "yo": "Nínú oṣù méjì tó kọjá nìkan, mẹ́wàá nínú àwọn arákùnrin àti àwọn arábìnrin wọ̀nyí ni wọ́n dá lẹ́bi. Àmọ́, wọn ò tíì fi wọ́n sẹ́wọ̀n báyìí.\"" }
{ "en": "\"On Friday, August 30, 2019, Brother Valeriy Moskalenko delivered his concluding comments to the court.", "yo": "\"Ní Friday, August 30, 2019, Arákùnrin Valeriy Moskalenko sọ ọ̀rọ̀ àsọkágbá rẹ̀ fún ilé ẹjọ́." }
{ "en": "The following is a partial transcript (translated from Russian) of his testimonial:", "yo": "Díẹ̀ rèé (tá a túmọ̀ láti èdè Rọ́ṣíà) lára ọ̀rọ̀ tó sọ níwájú ilé ẹjọ́:" }
{ "en": "Your Honor and distinguished attendants, I am 52 years old and the past year I have been kept in custody.", "yo": "Ọ̀gá Àgbà àti gbogbo ẹ̀yin ọlọ́lá tó wà níkàlẹ̀, ọmọ ọdún méjìléláàádọ́ta (52) ni mí, ọdún tó kọjá yìí ni wọ́n fi mí sí àtìmọ́lé." }
{ "en": "To be exact, it has been over a year now.", "yo": "Tàbí kí n kúkú sọ ní tààràtà pé ó ti lé ní ọdún kan báyìí." }
{ "en": "In my final words at this court session, I want to tell you briefly about myself, how I view the criminal charges, and about my personal view of life.", "yo": "Nínú ọ̀rọ̀ àsọkágbá mi fún ilé ẹjọ́ yìí, mo fẹ́ ṣàlàyé ṣókí fún yín nípa ara mi, ojú ti mo fi wo ẹ̀sùn ọ̀daràn tí wọ́n fi kàn mí àti ọwọ́ tí mo fi mú ìwàláàyè." }
{ "en": "I hope very much that you, Your Honor, will understand why I will not renounce my faith in God and why believing in God is not a crime.", "yo": "Ọ̀gá Àgbà, mo nírètí pé ẹ máa lóye ìdí ti mi ò fi ní sẹ́ ìgbàgbọ́ tí mo ní nínú Ọlọ́run àti ìdí kò fi sí ẹ̀ṣẹ̀ nínú kéèyàn gba Ọlọ́run gbọ́." }
{ "en": "I have not always been one of Jehovah’s Witnesses.", "yo": "Ẹlẹ́rìí Jèhófà kọ́ ni mí látilẹ̀ wá." }
{ "en": "My parents were kind and gave me a good upbringing, but even as a child it bothered me that there was so much injustice everywhere.", "yo": "Èèyàn rere làwọn òbí mi wọ́n sì kọ́ mi dáadáa, síbẹ̀ látìgbà tí mo ti wà lọ́mọdé ló ti máa ń dùn mí pé ìwà ìrẹ́jẹ kún ibi gbogbo." }
{ "en": "I thought, ‘This is not the way it should be—evil people and deceivers flourish, and honest and kind people suffer.’", "yo": "Mo máa ń ronú pé, ‘Kì í ṣe bó ṣe yẹ kí nǹkan rí nìyí, àwọn ẹni ibi àtàwọn ẹlẹ́tàn ń gbèrú, àwọn olóòótọ́ àti ẹni rere sì ń jìyà.’" }
{ "en": "At the age of 24, having seriously researched and studied the Bible for several months, I found answers to my questions.", "yo": "Nígbà tí mo wà lọ́mọ ọdún mẹ́rìnlélógún (24), mo ṣèwádìí gan-an nínú Bíbélì fún ọ̀pọ̀ oṣù, mo sì rí ìdáhùn sí àwọn ìbéèrè mi." }
{ "en": "Since then, I have been trying to make decisions that take into account God’s feelings, laws, and principles, which are described in detail", "yo": "Àtìgbà ló ti jẹ́ pé kí n tó ṣe ìpinnu, mo kọ́kọ́ máa ń ronú nípa ojú tí Ọlọ́run á fi wo ohun tí mo fẹ́ ṣe, màá sì tún ronú nípa àwọn òfin àti ìlànà rẹ̀." }
{ "en": "[in the Bible] and are exemplified in the lives of [worshippers] who lived in the past.", "yo": "[Bíbélì] ṣàlàyé àwọn òfin àti ìlànà náà ní kíkún, èèyàn sì lè mọ púpọ̀ sí i nípa wọn téèyàn bá kẹ́kọ̀ọ́ nípa àwọn tó sin Ọlọ́run nígbà àtijọ́." }
{ "en": "I live with my mother in the same flat.", "yo": "Inú ilé kan náà ni èmi àti màmá mi ń gbé." }
{ "en": "She is elderly and needs my care.", "yo": "Wọ́n ti dàgbà, ó sì yẹ kí n máa tọ́jú wọn." }
{ "en": "On August 1, 2018, when my mother was home alone, the Federal Security Service (FSB) investigator instructed the Special Forces to saw through the hinges of our front door.", "yo": "Ní August 1, 2018, nígbà tí màmá mi nìkan wà nínú ilé, Àwọn Òṣìṣẹ́ Aláàbò ti Ìjọba (FSB) tí wọ́n ń ṣe iṣẹ́ ìwádìí sọ fún Àwọn Ọlọ́pàá Àkànṣe pé kí wọ́n fi ayùn rẹ́ ilẹ̀kùn iwájú ìta ilé wa kúrò lára férémù." }
{ "en": "This is the way the investigator intended to enter my flat to conduct a search.", "yo": "Ọ̀nà tí ẹni tó wá ṣèwádìí náà yàn láti gbà wọnú ilé mí nìyẹn o." }
{ "en": "My mother was very frightened.", "yo": "Ẹ̀rù ba màmá mi gan-an." }
{ "en": "After the masked Special Forces broke into our flat, my mother had a heart attack and an ambulance had to be called.", "yo": "Lẹ́yìn tí Àwọn Ọlọ́pàá Àkànṣe tó da aṣọ bojú náà já wọnú ilé wa, àyà màmá mi jà débi pé wọ́n ní àrùn ọkàn wọ́n sì ní láti pe áńbúláǹsì kó wá gbé wọn." }
{ "en": "Upon learning that the police were in my home, I arrived 30 minutes later.", "yo": "Ọgbọ̀n ìṣẹ́jú lẹ́yìn tí mo gbọ́ pé àwọn ọlọ́pàá ti lọ sí ilé wa ni mo pa dà délé." }
{ "en": "When I saw my mother’s condition, my own blood pressure spiked.", "yo": "Nígbà tí mo rí ipò tí màmá mi wà, ìfúnpá tèmi náà ga sí i. Láìka gbogbo èyí sí, mi ò fi ṣèbínú, ṣe ni mo fọwọ́ wọ́nú." }
{ "en": "Despite all this, I did not get angry and I tried to maintain my composure. I was kind—as befits a Christian.", "yo": "Mò ń fi ìfẹ́ hùwà, bó ṣe yẹ kí Kristẹni ṣe." }
{ "en": "My God, Jehovah, taught me that and I don’t want to displease him.", "yo": "Ohun tí Jèhófà, Ọlọ́run mi fi kọ́ mi nìyẹn, mi ò sì fẹ́ ṣe ohun tó máa mú un bínú." }
{ "en": "I’m sorry, your Honor, I usually don’t talk about myself this much.", "yo": "Ẹ forí jì mí, Ọ̀gá Àgbà, èmi kì í sọ̀rọ̀ nípa ara mi tó báyìí." }
{ "en": "It’s not my habit, but now I must do so.", "yo": "Kì í ṣe ìwà mi, ọ̀rọ̀ ló bá mo-kó-mo-rò wá o." }
{ "en": "I have been one of Jehovah’s Witnesses for over 25 years.", "yo": "Ó lé ní ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n (25) tí mo ti di Ẹlẹ́rìí Jèhófà." }
{ "en": "That is a large portion of my life.", "yo": "Ẹ̀sìn tí mo fi èyí tó pọ̀ jù nínú ìgbésí ayé mi ṣe nìyẹn." }
{ "en": "And all this time I have never been considered an extremist.", "yo": "Látìgbà tí mo sì ti ń ṣe ẹ̀sìn náà, kò sẹ́ni tó kà mí sí agbawèrèmẹ́sìn rí." }
{ "en": "On the contrary, I was known as a good neighbor, a conscientious worker, and a caring son.", "yo": "Kàkà bẹ́ẹ̀, aládùúgbò rere làwọn èèyàn kà mí sí, ẹni tó ń fi tọkàntọkàn ṣiṣẹ́ àti ọmọ tó ń tọ́jú òbí ẹ̀." }
{ "en": "Suddenly, since April 20, 2017, I have been called an extremist.", "yo": "Ṣàdédé ni wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í pè mí ní agbawèrèmẹ́sìn láti April 20, 2017." }
{ "en": "On what grounds?", "yo": "Torí kí ni?" }
{ "en": "What has changed?", "yo": "Ìwà búburú wo ní wọ́n bá lọ́wọ́ mi?" }
{ "en": "Have I become worse? No.", "yo": "Ṣé mo ti ń hùwà àìdá ni? Rárá o." }
{ "en": "Have I become violent or caused someone pain and suffering? No.", "yo": "Ṣé mo ti di oníwà ipá ni àbí mo ti di ẹni tó ń fi ìyà jẹ àwọn míì tó sì ń fa ìrora fún wọn? Rárá o." }
{ "en": "Have I lost the right to avail myself of Article 28 of the Russian Constitution?", "yo": "Ṣé mi ò lẹ́tọ̀ọ́ láti jàǹfààní ohun tí Abala Kejìdínlọ́gbọ̀n nínú Òfin Orílẹ̀-Èdè Rọ́ṣíà sọ ni?" }
{ "en": "Also no.", "yo": "Rárá nìyẹn náà." }
{ "en": "My name was not listed in the decision of the Supreme Court.", "yo": "Orúkọ mi ò sí lára àwọn tí Ilé Ẹjọ́ Gíga Jù Lọ gbọ́ ẹjọ́ wọn." }
{ "en": "Nobody has deprived me of the right to use the Constitution of the Russian Federation, in particular Article 28.", "yo": "Kò sẹ́ni tó gba ẹ̀tọ́ àtilo Òfin Orílẹ̀-Èdè Rọ́ṣíà lọ́wọ́ mi, pàápàá jù lọ Abala Kejìdínlọ́gbọ̀n." }
{ "en": "Then why am I here at the defendant’s bench?", "yo": "Kí ló wá sọ mí di ẹni tó ń jẹ́jọ́ nílé ẹjọ́?" }
{ "en": "From my conversations with the investigator, it became even more evident that I was arrested and held in custody because I am a believer who uses the name of the Almighty God, Jehovah, in my prayers and speech.", "yo": "Nínú ọ̀rọ̀ tí èmi àti olùṣèwádìí jọ sọ, ó túbọ̀ ṣe kedere pé torí pé mo gba Jèhófà, Ọlọ́run Olódùmarè gbọ́ mo sì ń lo orúkọ rẹ̀ nínú àdúrà àti ọ̀rọ̀ mi ni wọ́n ṣe mú mi tí wọ́n sì fi mí sí àtìmọ́lé." }
{ "en": "But this is not a crime.", "yo": "Àmọ́, ẹ̀ṣẹ̀ ò sí nínú ìyẹn." }
{ "en": "God himself has chosen his name and made sure that it was recorded in the Bible.", "yo": "Ọlọ́run ló sọ ara rẹ̀ lórúkọ, tó sì rí i dájú pé orúkọ náà wà nínú Bíbélì." }
{ "en": "I repeat again and again, it is completely unthinkable for me to go against the will of God that is clearly expressed in the Bible.", "yo": "Mò ń sọ ọ́ léraléra pé mi ò ní ta ko ohun tí Ọlọ́run bá pa láṣẹ lọ́nà tó ṣe kedere nínú Bíbélì." }
{ "en": "And regardless of how I might be pressured or punished—even if I were sentenced to death—I declare that not even then would I abandon the almighty Creator of the universe, Jehovah God.", "yo": "Bó sì ti wù kéèyàn yọ mí lẹ́nu tàbí kó jẹ mí níyà tó, kódà tí wọ́n bá dájọ́ ikú fún mi, mo fẹ́ kó di mímọ̀ pé mi ò ní fi Jèhófà Ọlọ́run, Ẹlẹ́dàá ayé òun ọ̀run sílẹ̀ láé." }
{ "en": "Your Honor, Jehovah’s Witnesses are known throughout the world as friendly and peace-loving people.", "yo": "Ọ̀gá Àgbà, ibi gbogbo kárí ayé ni wọ́n ti mọ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà sí ẹni tó dùn ún bá rìn àti ẹni tó nífẹ̀ẹ́ àlàáfíà." }
{ "en": "Their rights as believers are respected in the vast majority of countries around the world.", "yo": "Ní ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè kárí ayé, wọ́n kì í fi ẹ̀tọ́ tí wọ́n ní láti gba Ọlọ́run gbọ́ dù wọ́n." }
{ "en": "I would very much like the rights of believers to be respected in Russia as well and, in this instance, my rights as a believer.", "yo": "Ó máa wù mí pé ká má ṣe fi ẹ̀tọ́ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà dù wọ́n ní orílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà náà, kò sì ní yẹ kí ilé ẹjọ́ yìí fi ẹ̀tọ́ tí mo ní láti gba Ọlọ́run gbọ́ dù mí." }
{ "en": "I am not guilty of the crime of which I am accused and I ask the court to render a not guilty verdict!", "yo": "Mi ò jẹ̀bi ẹ̀sùn tí wọ́n fi kàn mí, mo sì rọ ilé ẹjọ́ yìí láti má ṣe dá mi lẹ́bi!" }
{ "en": "Thank you!\"", "yo": "Ẹ ṣeun!\"" }
{ "en": "\"A United Nations (UN) panel of international legal experts has concluded that Russia’s arrest and detention of Brother Dmitriy Mikhaylov was “discriminatory on the basis of religion” and thus violated international law.", "yo": "\"Àwọn ọ̀jọ̀gbọ́n lórí ọ̀rọ̀ òfin ti àjọ Ìṣọ̀kan Àgbáyé ti sọ pé bí ìjọba Rọ́ṣíà ṣe fàṣẹ ọba mú Arákùnrin Dmitriy Mikhaylov tí wọ́n sì fi í sẹ́wọ̀n “nítorí ohun tó gbà gbọ́ fi hàn pé wọ́n hùwà àìtọ́ sí i,” wọ́n sì ti tẹ òfin àpapọ̀ àwọn ìjọba lójú." }
{ "en": "They also urged Russia to drop all criminal charges against Brother Mikhaylov.", "yo": "Àwùjọ àwọn ọ̀jọ̀gbọ́n náà tún rọ ìjọba Rọ́ṣíà pé wọn ò gbọ́dọ̀ fẹ̀sùn ìwà ọ̀daràn èyíkéyìí kan Arákùnrin Mikhaylov mọ́." }
{ "en": "According to the 12-page opinion of the panel, the Working Group on Arbitrary Detention (WGAD), Brother Mikhaylov’s actions “have always been entirely peaceful.”", "yo": "Ó tó ojú ìwé méjìlá tí ìgbìmọ̀ tí wọ́n ń pè ní Working Group on Arbitrary Detention (WGAD) fi kọ èrò wọn nípa Arákùnrin Mikhaylov, wọ́n sọ pé “kò sígbà tó ṣe ohun tó dí àlàáfíà ìlú lọ́wọ́.”" }
{ "en": "Additionally, “there is no evidence that he or indeed the Jehovah’s Witnesses in the Russian Federation have ever been violent or incited others to violence.”", "yo": "Yàtọ̀ síyẹn, “kò sí ẹ̀rí kankan tó fi hàn pé òun tàbí Ẹlẹ́rìí Jèhófà èyíkéyìí lórílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà jẹ́ oníwà ipá, wọn kì í sì í rọ àwọn míì pé kí wọ́n hùwà ipá.”" }
{ "en": "The WGAD concluded that Brother Mikhaylov “did nothing more than exercise his right to freedom of religion” and “should not have been arrested and held in pretrial detention.”", "yo": "Ìgbìmọ̀ WGAD wá pinnu pé ńṣe ni Arákùnrin Mikhaylov “kàn lo ẹ̀tọ́ tó ní láti ṣe ìsìn tó wù ú” kò sì “yẹ kí wọ́n fàṣẹ ọba mú un débi tí wọ́n á fi jù ú sí àhámọ́ láìgbọ́ ẹjọ́ ẹ̀.”" }
{ "en": "Therefore, he is entitled to compensation for his lost wages as well as for his personal loss of freedom while he was unlawfully detained.", "yo": "Nítorí náà, ó yẹ kí ìjọba san owó ìtanràn fún un torí pé kò ráyè ṣiṣẹ́ ní gbogbo àkókò tó fi wà lẹ́wọ̀n, àti pé wọ́n jù ú sẹ́wọ̀n láì jẹ̀bi ẹ̀sùn tí wọ́n fi kàn án." }
{ "en": "The WGAD also recognized that Brother Mikhaylov is not alone in suffering injustice for his faith.", "yo": "Ìgbìmọ̀ WGAD tún kíyè sí i pé kì í ṣe Arákùnrin Mikhaylov nìkan ni wọ́n ń fìyà jẹ nítorí ohun tó gbà gbọ́." }
{ "en": "He is “only one of the now ever-growing number of Jehovah’s Witnesses in the Russian Federation who have been arrested, detained, and charged with criminal activity on the basis of mere exercise of freedom of religion”—a right protected by international law.", "yo": "Òun náà jẹ́ “ọ̀kan lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà lórílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà tí wọ́n fàṣẹ ọba mú, tí wọ́n fi sẹ́wọ̀n, tí wọ́n sì ti fẹ̀sùn ìwà ọ̀daràn kàn nítorí pé wọ́n ń lo ẹ̀tọ́ tí wọ́n ní láti ṣe ìsìn tó wù wọ́n,” ó sì jẹ́ ẹ̀tọ́ tí òfin àpapọ̀ àwọn ìjọba fọwọ́ sí." }
{ "en": "Thus, in an effort to condemn the broader persecution of our fellow worshippers in Russia, the WGAD explicitly stated that their opinion applied not only to Brother Mikhaylov’s wrongful detention but to all Jehovah’s Witnesses who are “in situations similar to that of Mr. Mikhaylov.”", "yo": "Torí náà, ìgbìmọ̀ WGAD jẹ́ kó ṣe kedere pé kì í ṣe Arákùnrin Mikhaylov nìkan lọ̀rọ̀ yìí kàn, ó tún kan bí wọ́n ṣe ń fi gbogbo àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà sẹ́wọ̀n láìtọ́ “lọ́nà tó jọ ti Ọ̀gbẹ́ni Mikhaylov.”" }
{ "en": "Brother Mikhaylov began studying the Bible as a teenager and was baptized in 1993, when he was 16 years old.", "yo": "Ọ̀dọ́ ni Arákùnrin Mikhaylov nígbà tó bẹ̀rẹ̀ sí kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, ó sì ṣèrìbọmi nígbà tó pé ọmọ ọdún mẹ́rìndínlógún (16) lọ́dún 1993." }
{ "en": "In 2003, he married Yelena, and they began serving Jehovah together.", "yo": "Lọ́dún 2003, ó fẹ́ Yelena, àwọn méjèèjì sì jọ ń sin Jèhófà." }
{ "en": "In 2018, Brother and Sister Mikhaylov discovered that the authorities had been tapping their phones and had them under video surveillance for several months.", "yo": "Lọ́dún 2018, Arákùnrin àti Arábìnrin Mikhaylov kíyè sí i pé fún ọ̀pọ̀ oṣù làwọn aláṣẹ ti ń ṣọ́ wọn ni ti pé wọ́n ń tẹ́tí sí ọ̀rọ̀ wọn lórí fóònù, wọ́n sì tọ́jú kámẹ́rà sílé wọn." }
{ "en": "On April 19, 2018, the Investigation Committee of the Russian Federation in the Ivanovo region opened a criminal case against Brother Mikhaylov and heavily armed officers came to search his home.", "yo": "Ní April 19, 2018, Ìgbìmọ̀ Tó Ń Ṣèwádìí ní Àgbègbè Ivanovo Lórílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà fẹ̀sùn ìwà ọ̀daràn kan Arákùnrin Mikhaylov, làwọn ọlọ́pàá tó dira ogun bá lọ tú ilé rẹ̀ yẹ́bẹ́yẹ́bẹ́." }
{ "en": "A little over a month later, he was arrested and detained, under the claim of financing “extremist” activity.", "yo": "Kò ju oṣù kan lẹ́yìn ìyẹn, wọ́n fàṣẹ ọba mú un wọ́n sì jù ú sẹ́wọ̀n, wọ́n fẹ̀sùn kàn án pé ó ń fi owó ṣètìlẹ́yìn fáwọn “agbawèrèmẹ́sìn.”" }
{ "en": "After spending nearly six months—171 days—in pretrial detention, he was released.", "yo": "Wọ́n tú u sílẹ̀ lẹ́yìn tó ti fẹ́rẹ̀ẹ́ lo oṣù mẹ́fà lẹ́wọ̀n." }
{ "en": "However, his travel and communication are restricted for as long as the authorities keep his criminal investigation open.", "yo": "Torí pé ìwádìí ṣì ń lọ lọ́wọ́ lórí ẹjọ́ rẹ̀, àwọn aláṣẹ ò jẹ́ kó rìnrìn-àjò, wọ́n sì ń ṣọ́ ọ lọ́wọ́ lẹ́sẹ̀ bó ṣe ń bá àwọn èèyàn sọ̀rọ̀." }
{ "en": "The Russian government has six months to respond to the WGAD’s opinion in which they must state whether the criminal case against Mikhaylov has been closed, whether compensation has been provided, and whether the violators of his rights have been investigated.", "yo": "Oṣù mẹ́fà ni ìjọba ilẹ̀ Rọ́ṣíà ní láti fèsì lórí ìpinnu tí ìgbìmọ̀ WGAD ṣe, wọ́n gbọ́dọ̀ jẹ́ kí ìgbìmọ̀ náà mọ̀ bóyá ẹ̀sùn ìwà ọ̀daràn tí wọ́n fi kan Mikhaylov ti parí, bóyá wọ́n ti san owó ìtanràn fún un, bóyá wọ́n sì ti ṣèwádìí nípa àwọn tó fìyà jẹ ẹ́ láìṣẹ̀." }
{ "en": "A similar WGAD opinion likely effected change in the case of Brother Teymur Akhmedov from Kazakhstan.", "yo": "Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ìpinnu tí ìgbìmọ̀ WGAD ṣe yìí ló mú kí ìjọba orílẹ̀-èdè Kazakhstan dá Arákùnrin Teymur Akhmedov sílẹ̀ lẹ́wọ̀n." }
{ "en": "In 2017, he was arrested and subsequently sentenced to a five-year term for peacefully sharing his faith with others.", "yo": "Lọ́dún 2017, wọ́n fàṣẹ ọba mú un, wọ́n sì rán an lọ sí ẹ̀wọ̀n ọdún márùn-ún torí pé ó ń sọ ohun tó gbà gbọ́ fáwọn ẹlòmíì láìfi dí àlàáfíà ìlú lọ́wọ́." }
{ "en": "Having exhausted all domestic remedies, lawyers for Brother Akhmedov filed a complaint with the WGAD.", "yo": "Gbogbo ilé ẹjọ́ tó wà ní Kazakhstan ni wọ́n gbé ẹjọ́ náà lọ, àmọ́ kò lójú, ni agbẹjọ́rò Arákùnrin Akhmedov bá gbé ẹjọ́ náà lọ sọ́dọ̀ ìgbìmọ̀ WGAD." }
{ "en": "In their opinion dated October 2, 2017, the WGAD condemned the actions of the Kazakh authorities and called for Brother Akhmedov’s release.", "yo": "Nínú ìpinnu tí ìgbìmọ̀ WGAD ṣe ní October 2, 2017, wọ́n ní ìwà tí àwọn aláṣẹ orílẹ̀-èdè Kazakhstan hù kò dáa, wọ́n sì ní kí wọ́n tú Arákùnrin Akhmedov sílẹ̀." }
{ "en": "Six months later, the president of Kazakhstan pardoned Brother Akhmedov.", "yo": "Lẹ́yìn oṣù mẹ́fà, ààrẹ orílẹ̀-èdè Kazakhstan wá sọ ọ́ ní gbangba pé Arákùnrin Akhmedov kì í ṣe ọ̀daràn." }
{ "en": "He was released from custody on April 4, 2018.", "yo": "Ní April 4, 2018, wọ́n dá a sílẹ̀ lẹ́wọ̀n." }
{ "en": "Regardless of how Russia responds to the decision of the WGAD in Brother Mikhaylov’s case, our full trust is in the promise: “Happy is the man who takes refuge in [Jehovah].”", "yo": "Yálà orílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà máa ṣe ohun tí ìgbìmọ̀ WGAD ní kí wọ́n ṣe fún Arákùnrin Mikhaylov tàbí wọn ò ní ṣe bẹ́ẹ̀, ọkàn wa balẹ̀ torí Bíbélì sọ pé: “Aláyọ̀ ni ọkùnrin tí ó fi [Jèhófà] ṣe ibi ààbò.”" }
{ "en": "We pray that Jehovah continues to care for our brothers and sisters in Russia who face criminal action, so they will further experience how all who courageously trust in Him “will lack nothing good.”—Psalm 34:8, 10.", "yo": "Àdúrà wa ni pé kí Jèhófà máa bójú tó àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin wa tí wọ́n ń fi ẹ̀sùn ìwà ọ̀daràn kàn ní Rọ́ṣíà, kí wọ́n lè rí i pé gbogbo ẹni tó bá nígboyà tó sì gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà kò ní “ṣaláìní ohun rere.”​—⁠Sáàmù 34:​8, 10." }
{ "en": "A UN panel of five international experts mandated to investigate cases of detention that are inconsistent with international standards set forth in the Universal Declaration of Human Rights and other international documents.", "yo": "Ó jẹ́ ìgbìmọ̀ àwọn ọ̀jọ̀gbọ́n ẹlẹ́ni márùn-ún tí àjọ Ìṣọ̀kan Àgbáyé dá sílẹ̀, kí wọ́n lè máa ṣèwádìí àwọn tí ìjọba rán lọ sẹ́wọ̀n lọ́nà àìtọ́." }
{ "en": "In order to establish the facts, the Working Group on Arbitrary Detention (WGAD) has the right to receive information from the authorities and nongovernmental organizations.", "yo": "Ìgbìmọ̀ náà máa pinnu bóyá ìjọba ti tàpá sí òfin tí àpapọ̀ àwọn ìjọba là kalẹ̀ bó ṣe wà nínú Ìwé Ìpolongo Ẹ̀tọ́ Ọmọnìyàn Lágbàáyé àtàwọn ìwé míì." }
{ "en": "It also may meet with detainees and members of their families.", "yo": "Kí wọ́n ba à lè fìdí òtítọ́ múlẹ̀, ìgbìmọ̀ Working Group on Arbitrary Detention (WGAD) lẹ́tọ̀ọ́ láti wádìí ọ̀rọ̀ lọ́dọ̀ àwọn aláṣẹ àtàwọn iléeṣẹ́ tí kì í ṣe ti ìjọba kí wọ́n lè gba ìsọfúnni tí wọ́n nílò." }
{ "en": "The WGAD presents its conclusions and recommendations to governments, as well as to the UN Human Rights Council.", "yo": "Ó tiẹ̀ lè gba pé kí wọ́n rí ẹni tí wọ́n fi sẹ́wọ̀n náà àti ìdílé rẹ̀. Lẹ́yìn náà, ìgbìmọ̀ WGAD á wá sọ ìpinnu àti àbá wọn fún ìjọba títí kan Àjọ Ẹ̀tọ́ Ọmọnìyàn ti Àjọ Ìṣọ̀kan Àgbáyé." }
{ "en": "Although the opinions of the WGAD are not enforceable, they are often publicized and can generate international attention, which may influence world leaders to adhere to international law.\"", "yo": "Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ìgbìmọ̀ WGAD ò lè fi dandan lé e pé kí ìjọba tẹ̀ lé ìpinnu wọn, wọ́n máa ń jẹ́ kí gbogbo èèyàn lágbàáyé mọ ìpinnu tí wọ́n bá ṣe. Ìyẹn sì lè mú káwọn aláṣẹ tẹ̀ lé ìpinnu wọn.\"" }
{ "en": "\"Andrzej Oniszczuk, a Polish citizen and one of our dear brothers, has been in pretrial detention in Russia since security forces arrested him on October 9, 2018.", "yo": "\"Láti October 9, 2018 táwọn agbófinró ti mú Anrzej Oniszczuk, tó jẹ́ ọmọ orílẹ̀-èdè Poland àti arákùnrin kan, wọn ò tíì gbọ́ ẹjọ́ wọn títí di báyìí." }
{ "en": "His detention was recently extended for the fifth time.", "yo": "Ẹ̀karùn-ún rèé tí wọ́n máa sún àkókò tó fi wà látìmọ́lé síwájú." }
{ "en": "His new term is scheduled to end on October 2, just days short of a year incarcerated.", "yo": "October 2 ni wọ́n ṣètò pé kó parí àtìmọ́lé rẹ̀, ìyẹn ọjọ́ díẹ̀ kó pé ọdún kan tó ti wà ní àhámọ́." }
{ "en": "Andrzej, prior to being arrested, with his wife, Anna.", "yo": "Arákùnrin Andrzej àti ìyàwó rẹ̀ Anna, ṣáájú kí wọ́n tó mú un lọ sí àtìmọ́lé." }
{ "en": "She has not been allowed to visit him since his arrest ten months ago", "yo": "Wọn ò gba Anna láyè láti rí ọkọ rẹ̀ láti oṣù mẹ́wàá sẹ́yìn" }